DIDACTIVE 'ÌBÍNÚ'
Àìsàn burúkú ni ìbínú jẹ́...
Kò dára bẹ́ẹ̀ ni kò sunwọ̀n....
Ìbínú yára pànìyàn...
Ìbínú rán ènìyàn lọ sí ibi tí kò tọ́....
Ìbínú kìí tún nǹkan ṣe ó máa ń ba nǹkan jẹ́ ni....
Ohun tí èèyàn ti lé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún...
Ìbínú a máa bàájẹ́ ní ọjọ́ kan...
Ìbínú a máa lé olóore jìnà síni...
Inú bíbí a máa fa wàhálà síni lọ́run...
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni inú bíbí ti sìn dé ọgbà ẹ̀wọ̀n...
Ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló ti foríṣọ́pọ́n ní pa inú bíbí
Ọ̀pọ̀ obìnrin ló ti lọ dálémoṣú nípasẹ̀ inú bíbí
Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló ti di Àpọ́n ọ̀sán gangan ní pa àìsàn inú àbíjù....
Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ìjọba ni wọ́n ti fún ní ìwé gbé lé ẹ nípasẹ̀ inú bíbí
Ọ̀pọ̀ oníșẹ́ ọwọ́ ló ti lé àwọn oníbáárà ní pa aṣọ ìbínú tí ó gbé wọ̀...
Bí ìwọ náà bá wá jẹ́ ẹni tí ó máa ń bínú jù...
Yálà ọkùnrin ni Ọ́ tàbí obìnrin.... Yára lọ wá àtúnṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ...
Kí ìwọ náà lọ ní sùúrù bí ilẹ̀....
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀gbin ni à ń ṣe sí ilẹ̀.... Síbẹ̀ omi tómọ́ ló ń sun jáde fún wa.....
Gbogbo ibikíbi tí o bá ń lọ máa rántí pé..
Ìbínú kìí fa ire mọ́ra...
SÙÚRÙ KÌÍ PỌ̀JÙ ÀYÀFI TÍ KÒ BÁ NÍ TÓ...
(Anonymous)
The bard says anger should be avoided and it kills faster than a bullet. Patience is never in excess, it can only be insufficient.
Post a Comment